Histoire 1
Iwé Maki, 4 : 35-41
JÉSU PASẸ FU OFUFU KILÉ LOKUN
Maki 4, 35-41 Mix
35 Ejẹ ẹ yẹ lalẹ papa, Jésu fϙfu ϙma-añi ẹ ya ni : « ka lϙ lataké odo. »
36 An didé fu kipϙ anian ya jϙϙ ; ϙma-añi ya gbin Jésu lapamba. N’non apamba yé Jésu joko ẹ apamba bibϙ ya wa pẹki i.
37 Bẹni ofufu kilé-kilé kan bẹsi kifẹ, omi ya ako dasi lϙ lϙsϙ apamba, dé ipo ni ϙbẹsi kikon fu omi.
38 Jésu fi éwo lé latanfu kan osun a sohun nañi apamba. Ϙma-añi ẹ ya kusi fuji i : « Ϙgan, akaku : i koyi si ? »
39 Jésu ji, ni ϙpas ẹ fu ofufu, ϙ fϙfu omi adagu ni : « siko ! jokojẹ ! » Bẹni ofufu yẹ da dio ni idi sé juu.
40 Ni Jésu afϙfu ϙma-añi ẹ ya ni : « kese gbo ojo a se yin bẹni ? Fudi isin ẹkẹnẹ igbϙkanléaa ? »
41 Ama ojo se ya paa ni aya fϙ liméji ara ya ni : « ẹnin bi ési ni yé i, gbo odi ni omi wu ofufu ya agbϙ tẹẹ ni ? »
Histoire 2
wé ϙbayan ekeji, éwo 4 ẹsẹ 1 fu dé 7
ÉLISÉ GBA ϘBUIN OPO
2 Rois 4, 1-7, Itan Elisé
1 Ϙbuin kan limeji ϙbuin ϙma ajisẹ Ϙlϙon ya kusi lϙba Elisé, ϙfϙfύ ni: ϙma isẹ ϙkϙmi ti ku ni ϙmá ni ϙma isẹ ẹ a sa fu Ϙluwa, bẹni ẹlẹñin sin wa kϙ wa ko ϙmami ya lϙ ni kolofu ya sé aru
2 Elisé bi i ni kéi matiko sé fẹ ni? Kéi ϙnin n’lé fϙfumi. Ϙda lohun ni ϙbuin ẹ kϙnin n’kankan n’lé pé épo koko kanso
3 Ni ϙfϙfύ ni wa tulϙ ndi aladogbo ẹ ya gudugudu ilϙ tϙ ẹ koko gbada ya , masé tϙẹ odé.
4 Bi osé ni olu n’kona tan ni ikankun di ara ẹ un ϙma ẹ ya; wa tu épo yẹ dasi lϙsϙ koko yẹ ya gudugudu, ni yé nkokon ya ẹ wa gbin ya sisi lapala kan
5 Bẹn’odidé n’di ẹ, ϙkankun di ara ẹ un ϙma ẹ ya; aya a gbin koko ya fu, ni a rϙ épo sisi n’nϙn ya
6 Yé gbo koko yẹ ya kon tan ẹ, ϙ fϙfu ϙma ẹ ni: gbin koko kan wa sin o, ama ϙda loun ni : koko kan kosi o, bẹni épo dadio
7 ϙ lϙfϙ ϙ fu onian ϙlϙon, ni ϙ fϙfύ ni: lϙ ta épo ni isan ẹñin ẹ ; ni wϙ un ϙma ẹ ya kẹ jẹ ye n’kϙbϙ ẹ
Histoire 3
IWÉ LUKU, ÉWO 19: 1-10
SAKÉU PADÉ JÉSU
Jésu padé Sakéu Luku 19, 1-10
1 Jésu wϙ ilu Jériko lϙ, á la igboo kϙja
2 Bẹn’ϙkϙnin yé gbo aya á pé ni Sakéu, ϙgan a gba lampo ya, a wo kϙma ésini Jésu
3 Ama kotiko ri. N’di n’onian ya pϙ, n’di n’onian pukulu n’ϙwa
4 Osué lϙ liwaju, n’ologu égi sikomoré kan ni kofu ri n’di ni m’bẹ ni n’kϙ gba kϙja
5 Yé Jésu dé lϙ gan-gan ẹ ẹ, ϙgbin oju loké n’ϙfϙfύ ni : Sakéu tiwa kϙya n’di n’ϙwa ni n’gbé n’lé ẹ oni
6 Sakéu ti kϙya-kϙya n’ϙf’ayϙ gbaa
7 Yé aya ri bẹ ẹ aya bẹsi ki kϙkonun gudu-gudu ya, n’aya fϙ ni : ϙlϙ ϙlϙ gbé n’lé ϙkonin ẹlẹsẹ kan
8 Ama Sakéu dio liwaju Ϙluwa, a fϙfu ni : yéni ẹ, maa mu idaji n’kan yé mϙnin ya ẹ fu ϙliya ya, ni b’oséni mo di oniankan sisi man san pada fu n’ϙna mẹin
9 Jésu fϙfύ ni : igbala wϙ lϙsϙ ilé yé oni, n’di ni ẹnin yé gbo ni ϙma Abrahamu
10 n’di n’ϙma onian wa kϙwa wo ni kϙgba n’kan yé ti ra ya ẹ la